Gẹn 5:23-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji:

24. Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ.

25. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki:

Gẹn 5