Gẹn 5:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela:

22. Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

23. Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji:

24. Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ.

25. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki:

26. Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

Gẹn 5