1. EYI ni iwe iran Adamu: Li ọjọ́ ti Ọlọrun dá ọkunrin, li aworan Ọlọrun li o dá a.
2. Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn.
3. Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti:
4. Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:
5. Gbogbo ọjọ́ ti Adamu wà si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé ọgbọ̀n: o si kú.
6. Seti si wà li ọgọrun ọdún o lé marun, o si bí Enoṣi:
7. Seti si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé meje lẹhin ti o bí Enoṣi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:
8. Ati gbogbo ọjọ́ Seti jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdun o lé mejila: o si kú.
9. Enoṣi si wà li ãdọrun ọdún, o si bí Kenani: