18. Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun.
19. Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini.
20. Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u.
21. Ati awọn ọmọ Benjamini; Bela, ati Bekeri, ati Aṣbeli, Gera, ati Naamani, Ehi, ati Roṣi, Muppimu, ati Huppimu, ati Ardi.
22. Wọnyi li awọn ọmọ Rakeli, ti a bí fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ mẹrinla.
23. Ati awọn ọmọ Dani; Huṣimu.
24. Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu.
25. Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje.