Gẹn 44:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Mú u sọkalẹ tọ̀ mi wá, ki emi ki o le fi oju mi kàn a.

22. Awa si wi fun oluwa mi pe, Ọdọmọde na kò le fi baba rẹ̀ silẹ: nitoripe bi o ba fi i silẹ, baba rẹ̀ yio kú.

23. Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Ayaṣebi arakunrin nyin abikẹhin ba bá nyin sọkalẹ wá, ẹnyin ki yio ri oju mi mọ́.

24. O si ṣe nigbati awa goke tọ̀ baba mi iranṣẹ rẹ lọ, awa sọ̀rọ oluwa mi fun u.

25. Baba wa si wipe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá.

26. Awa si wipe, Awa kò le sọkalẹ lọ: bi arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa, njẹ awa o sọkalẹ lọ; nitori ti awa ki o le ri oju ọkunrin na, bikoṣepe arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa.

27. Baba mi iranṣẹ rẹ si wi fun wa pe Ẹnyin mọ̀ pe aya mi bí ọmọ meji fun mi:

28. Ọkan si ti ọdọ mi jade lọ, mo si wipe, Nitõtọ a fà a ya pẹrẹpẹrẹ; emi kò si ri i lati igbana wá:

29. Bi ẹnyin ba si mú eyi lọ lọwọ mi pẹlu, ti ibi kan si ṣe e, ibinujẹ li ẹnyin o fi mú ewú mi lọ si isà-okú.

Gẹn 44