Gẹn 42:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Josefu si ri awọn arakunrin rẹ̀, o si mọ̀ wọn, ṣugbọn o fi ara rẹ̀ ṣe àjeji fun wọn, o si sọ̀rọ akọ si wọn: o si wi fun wọn pe, Nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, Lati ilẹ Kenaani lati rà onjẹ.

8. Josefu si mọ̀ awọn arakunrin rẹ̀, ṣugbọn awọn kò mọ̀ ọ.

9. Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá.

10. Nwọn si wi fun u pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, ṣugbọn lati rà onjẹ li awọn iranṣẹ rẹ ṣe wá.

11. Ọmọ ẹnikan na ni gbogbo wa iṣe; olõtọ enia li awa, awa iranṣẹ rẹ ki iṣe amí.

12. O si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn lati ri ìhoho ilẹ li ẹ ṣe wá.

13. Nwọn si wipe, Arakunrin mejila li awa iranṣẹ rẹ, ọmọ ẹnikan na ni ilẹ Kenaani: si wò o, eyi abikẹhin si wà lọdọ baba wa loni-oloni, ọkan kò si sí.

14. Josefu si wi fun wọn pe, On na li eyiti mo wi fun nyin pe, Amí li ẹnyin:

15. Eyi bayi li a o fi ridi nyin, nipa ẹmi Farao bi ẹnyin o ti lọ nihin, bikoṣepe arakunrin abikẹhin nyin wá ihinyi.

16. Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe.

17. O si kó gbogbo wọn pọ̀ sinu túbu ni ijọ́ mẹta.

Gẹn 42