1. O SI ṣe li opin ọdún meji ṣanṣan, ni Farao lá alá: si kiyesi i, o duro li ẹba odo.
2. Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò.
3. Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na.
4. Awọn abo-malu ti o buru ni wiwò ti o si rù si mú awọn abo-malu meje ti o dara ni wiwò ti o si sanra wọnni jẹ. Bẹ̃ni Farao jí.