Gẹn 40:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O si fi wọn sinu túbu ninu ile olori ẹṣọ́, sinu túbu ti a gbé dè Josefu si.

4. Olori ẹṣọ́ na si fi Josefu jẹ́ olori wọn; o si nṣe itọju wọn: nwọn si pẹ diẹ ninu túbu na.

5. Awọn mejeji si lá alá kan, olukuluku lá alá tirẹ̀ li oru kanna, olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀, agbọti ati alasè ọba Egipti, ti a dè sinu túba na.

6. Josefu si wọle tọ̀ wọn lọ li owurọ̀, o si wò wọn, si kiyesi i, nwọn fajuro.

7. O si bi awọn ijoye Farao ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ile túbu oluwa rẹ̀ pe, Ẽṣe ti oju nyin fi buru bẹ̃ loni?

8. Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi.

9. Olori agbọti si rọ́ alá tirẹ̀ fun Josefu, o si wi fun u pe, Li oju alá mi, kiyesi i, àjara kan wà niwaju mi,

Gẹn 40