Gẹn 40:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi, li agbọti ọba Egipti ati alasè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Egipti oluwa wọn.

2. Farao si binu si meji ninu awọn ijoye rẹ̀, si olori awọn agbọti, ati si olori awọn alasè.

3. O si fi wọn sinu túbu ninu ile olori ẹṣọ́, sinu túbu ti a gbé dè Josefu si.

4. Olori ẹṣọ́ na si fi Josefu jẹ́ olori wọn; o si nṣe itọju wọn: nwọn si pẹ diẹ ninu túbu na.

Gẹn 40