38. Ṣaulu si kú, Baal-hanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀.
39. Baal-hanani ọmọ Akbori si kú, Hadari si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pau; Mehetabeli si li orukọ aya rẹ̀, ọmọbinrin Metredi, ọmọbinrin Mesahabu.
40. Wọnyi si li orukọ awọn olori ti o ti ọdọ Esau wá, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ipò wọn, nipa orukọ wọn; Timna olori, Alfa olori, Jeteti olori;
41. Aholibama olori, Ela olori, Pinoni olori;
42. Kenasi olori, Temani olori, Mibsari olori;
43. Magdieli olori, Iramu olori: wọnyi li awọn olori Edomu, nipa itẹ̀dó wọn ni ilẹ iní wọn: eyi ni Esau, baba awọn ara Edomu.