Gẹn 36:32-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba.

33. Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.

34. Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀.

35. Huṣamu si kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ẹniti o kọlù Midiani ni igbẹ́ Moabu si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Afiti.

36. Hadadi si kú, Samla ti Masreka si jọba ni ipò rẹ̀.

37. Samla si kú, Ṣaulu ti Rehobotu leti odò nì si jọba ni ipò rẹ̀.

38. Ṣaulu si kú, Baal-hanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀.

39. Baal-hanani ọmọ Akbori si kú, Hadari si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pau; Mehetabeli si li orukọ aya rẹ̀, ọmọbinrin Metredi, ọmọbinrin Mesahabu.

40. Wọnyi si li orukọ awọn olori ti o ti ọdọ Esau wá, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ipò wọn, nipa orukọ wọn; Timna olori, Alfa olori, Jeteti olori;

Gẹn 36