24. Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀.
25. Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana.
26. Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani.
27. Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani.
28. Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani.