Gẹn 36:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu.

24. Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀.

25. Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana.

26. Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani.

27. Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani.

28. Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani.

29. Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori,

30. Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.

31. Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli.

Gẹn 36