Gẹn 36:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu.

2. Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi;

3. Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu.

4. Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli;

5. Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani.

Gẹn 36