11. Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá;
12. Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun.
13. Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ.
14. Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀.
15. Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.
16. Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u.
17. O si ṣe nigbati o wà ninu irọbí, ni iyãgba wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu.