Gẹn 31:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ Labani ti nwọn wipe, Jakobu kó nkan gbogbo ti iṣe ti baba wa; ati ninu ohun ti iṣe ti baba wa li o ti ní gbogbo ọrọ̀ yi.

2. Jakobu si wò oju Labani, si kiyesi i, kò ri si i bi ìgba atijọ.

3. OLUWA si wi fun Jakobu pe, Pada lọ si ilẹ awọn baba rẹ, ati si ọdọ awọn ara rẹ; emi o si pẹlu rẹ.

4. Jakobu si ranṣẹ o si pè Rakeli on Lea si pápa si ibi agbo-ẹran rẹ̀,

5. O si wi fun wọn pe, Emi wò oju baba nyin pe, kò ri si mi bi ìgba atijọ; ṣugbọn Ọlọrun baba mi ti wà pẹlu mi.

6. Ẹnyin si mọ̀ pe gbogbo agbara mi li emi fi sìn baba nyin.

7. Baba nyin si ti tàn mi jẹ, o si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa: ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ ki o pa mi lara.

8. Bi o ba si wi bayi pe, Awọn abilà ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí abilà: bi o ba si wi bayi, Awọn oni-tototó ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí oni-tototó.

9. Bẹ̃li Ọlọrun si gbà ẹran baba nyin, o si fi wọn fun mi.

Gẹn 31