Gẹn 30:33-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Ododo mi yio si jẹ mi li ẹrí li ẹhin-ọla nigbati iwọ o wá wò ọ̀ya mi: gbogbo eyiti kò ba ṣe abilà ati alami ninu awọn ewurẹ, ti kò si ṣe pupa rúsurusu ninu awọn agutan, on na ni ki a kà si mi li ọrùn bi olè.

34. Labani si wipe, Wò o, jẹ ki o ri bi ọ̀rọ rẹ.

35. Li ọjọ́ na li o si yà awọn obukọ oni-tototó ati alamì, ati gbogbo awọn ewurẹ ti o ṣe abilà ati alamì, ati gbogbo awọn ti o ní funfun diẹ lara, ati gbogbo oni-pupa rúsurusu ninu awọn agutan, o si fi wọn lé awọn ọmọ rẹ̀ lọwọ.

36. O si fi ìrin ọjọ́ mẹta si agbedemeji on tikalarẹ̀ ati Jakobu: Jakobu si mbọ́ agbo-ẹran Labani iyokù.

37. Jakobu si mú ọpá igi-poplari tutù, ati igi haseli, ati kesnuti; o si bó wọn li abófin, o si mu ki funfun ti o wà lara awọn ọpá na hàn.

38. O si fi ọpá ti o bó lelẹ niwaju awọn agbo-ẹran li oju àgbará, ni ibi ọkọ̀ imumi, nigbati awọn agbo-ẹran wá mu omi, ki nwọn ki o le yún nigbati nwọn ba wá mumi.

39. Awọn agbo-ẹran si yún niwaju ọpá wọnni, nwọn si bí ẹran oni-tototó, ati abilà, ati alamì.

40. Jakobu si yà awọn ọdọ-agutan, o si kọju awọn agbo-ẹran si oni-tototó, ati gbogbo onìpupa rúsurusu ninu agbo-ẹran Labani: o si fi awọn agbo-ẹran si ọ̀tọ fun ara rẹ̀, kò si fi wọn sinu ẹran Labani.

41. O si ṣe, nigbati ẹran ti o lera jù ba yún, Jakobu a si fi ọpá na lelẹ niwaju awọn ẹran na li oju àgbará, ki nwọn o le ma yún lãrin ọpá wọnni.

42. Ṣugbọn nigbati awọn ẹran ba ṣe alailera, on ki ifi si i; bẹ̃li ailera ṣe ti Labani, awọn ti o lera jẹ́ ti Jakobu.

43. ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si li ẹran-ọ̀sin pupọ̀, ati iranṣẹbinrin, ati iranṣẹkunrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.

Gẹn 30