23. O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Ọlọrun mú ẹ̀gan mi kuro:
24. O si pè orukọ rẹ̀ ni Josefu; o si wipe, Ki OLUWA ki o fi ọmọkunrin kan kún u fun mi pẹlu.
25. O si ṣe, nigbati Rakeli bí Josefu tán, Jakobu si wi fun Labani pe, Rán mi jade lọ, ki emi ki o le ma lọ si ibiti mo ti wá, ati si ilẹ mi.
26. Fun mi li awọn obinrin mi, ati awọn ọmọ mi, nitori awọn ẹniti mo ti nsìn ọ, ki o si jẹ ki nma lọ: iwọ sá mọ̀ ìsin ti mo sìn ọ.
27. Labani si wipe, Duro, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, joko: nitori ti mo ri i pe, OLUWA ti bukún fun mi nitori rẹ.
28. O si wi fun u pe, Sọ iye owo iṣẹ rẹ, emi o si fi fun ọ.
29. O si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ bi emi ti sìn ọ, ati bi ẹran-ọ̀sin rẹ ti wà lọdọ mi.
30. Diẹ ni iwọ sá ti ní ki nto dé ọdọ rẹ, OLUWA si busi i li ọ̀pọlọpọ fun ọ lati ìgba ti mo ti dé: njẹ nisisiyi nigbawo li emi o pèse fun ile mi?
31. O si bi i pe, Kili emi o fi fun ọ? Jakobu si wi pe, Iwọ máṣe fun mi li ohun kan: bi iwọ o ba le ṣe eyi fun mi, emi o ma bọ́, emi o si ma ṣọ́ agbo-ẹran rẹ.
32. Emi o là gbogbo agbo-ẹran rẹ já loni, emi o mú gbogbo ẹran abilà ati alamì kuro nibẹ̀, ati gbogbo ẹran pupa rúsurusu kuro ninu awọn agutan, ati gbogbo ẹran alamì ati abilà ninu awọn ewurẹ: eyi ni yio si ma ṣe ọ̀ya mi.
33. Ododo mi yio si jẹ mi li ẹrí li ẹhin-ọla nigbati iwọ o wá wò ọ̀ya mi: gbogbo eyiti kò ba ṣe abilà ati alami ninu awọn ewurẹ, ti kò si ṣe pupa rúsurusu ninu awọn agutan, on na ni ki a kà si mi li ọrùn bi olè.
34. Labani si wipe, Wò o, jẹ ki o ri bi ọ̀rọ rẹ.
35. Li ọjọ́ na li o si yà awọn obukọ oni-tototó ati alamì, ati gbogbo awọn ewurẹ ti o ṣe abilà ati alamì, ati gbogbo awọn ti o ní funfun diẹ lara, ati gbogbo oni-pupa rúsurusu ninu awọn agutan, o si fi wọn lé awọn ọmọ rẹ̀ lọwọ.
36. O si fi ìrin ọjọ́ mẹta si agbedemeji on tikalarẹ̀ ati Jakobu: Jakobu si mbọ́ agbo-ẹran Labani iyokù.
37. Jakobu si mú ọpá igi-poplari tutù, ati igi haseli, ati kesnuti; o si bó wọn li abófin, o si mu ki funfun ti o wà lara awọn ọpá na hàn.