22. Jakobu si sunmọ Isaaki baba rẹ̀, o si fọwọbà a, o si wipe, Ohùn Jakobu li ohùn, ṣugbọn ọwọ́ li ọwọ́ Esau.
23. On kò si mọ̀ ọ, nitoriti ọwọ́ rẹ̀ ṣe onirun, bi ọwọ́ Esau, arakunrin rẹ̀: bẹ̃li o sure fun u.
24. O si wipe, Iwọ ni Esau ọmọ mi nitotọ? o si wipe, emi ni.
25. O si wipe, Gbé e sunmọ ọdọ mi, emi o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ mi, ki ọkàn mi ki o le sure fun ọ. O si gbé e sunmọ ọdọ rẹ̀, o si jẹ: o si gbé ọti-waini fun u, on si mu.
26. Isaaki baba rẹ̀ si wi fun u pe, Sunmọ ihín nisisiyi ọmọ mi, ki o si fi ẹnu kò mi li ẹnu.
27. O si sunmọ ọ, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: o si gbọ́ õrùn aṣọ rẹ̀, o si sure fun u, o si wipe, Wò o, õrùn ọmọ mi o dabi õrùn oko eyiti OLUWA ti busi.
28. Ọlọrun yio si fun ọ ninu ìri ọrun, ati ninu ọrá ilẹ, ati ọ̀pọlọpọ ọkà ati ọti-waini:
29. Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ.
30. O si ṣe, bi Isaaki ti pari ire isú fun Jakobu, ti Jakobu si fẹrẹ má jade tan kuro niwaju Isaaki baba rẹ̀, ni Esau, arakunrin rẹ̀ wọle de lati igbẹ́ ọdẹ rẹ̀ wá.
31. On pẹlu si ti sè ẹran adidùn, o si mu u tọ̀ baba rẹ̀ wá, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Ki baba mi ki o dide ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ rẹ̀, ki ọkàn rẹ le sure fun mi.
32. Isaaki baba rẹ̀ si bi i pe, Iwọ tani nì? on si wipe, Emi Esau, ọmọ rẹ akọbi ni.
33. Isaaki si warìri gidigidi rekọja, o si wipe, Tani nla? tali ẹniti o ti pa ẹran-igbẹ́, ti o si gbé e tọ̀ mi wá, emi si ti jẹ ninu gbogbo rẹ̀, ki iwọ ki o to de, emi si ti sure fun u? nitõtọ a o si bukún fun u.
34. Nigbati Esau gbọ́ ọ̀rọ baba rẹ̀, o fi igbe nlanla ta, o si sun ẹkun kikorò gidigidi, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Sure fun mi, ani fun emi pẹlu, baba mi.
35. O si wipe, Arakunrin rẹ fi erú wá, o si ti gbà ibukún rẹ lọ.