Gẹn 24:21-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. ọkunrin na si tẹjumọ ọ, o dakẹ, lati mọ̀ bi OLUWA mu ìrin on dara, bi bẹ̃kọ.

22. O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa;

23. O si bi i pe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi: àye wà ni ile baba rẹ fun wa lati wọ̀ si?

24. On si wi fun u pe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Milka, ti o bí fun Nahori, li emi iṣe.

25. O si wi fun u pe, Awa ni koriko ati sakasáka tó pẹlu, ati àye lati wọ̀ si.

26. Ọkunrin na si tẹriba, o si sìn OLUWA.

27. O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi.

28. Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀.

29. Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga.

30. O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na.

31. O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ.

32. Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀.

Gẹn 24