Gẹn 23:18-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Fun Abrahamu ni ilẹ-ini, li oju awọn ọmọ Heti, li oju gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀.

19. Lẹhin eyi li Abrahamu sin Sara, aya rẹ̀, ninu ihò oko Makpela, niwaju Mamre: eyi nã ni Hebroni ni ilẹ Kenaani.

20. Ati oko na, ati ihò ti o wà nibẹ̀, li a ṣe daju fun Abrahamu, ni ilẹ isinku, lati ọwọ́ awọn ọmọ Heti wá.

Gẹn 23