Gẹn 23:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SARA si di ẹni ẹtadilãdoje ọdún: iye ọdún aiye Sara li eyi.

2. Sara si kú ni Kirjat-arba; eyi na ni Hebroni ni ilẹ Kenaani: Abrahamu si wá lati ṣọ̀fọ Sara ati lati sọkun rẹ̀.

3. Abrahamu si dide kuro niwaju okú rẹ̀, o si sọ fun awọn ọmọ Heti, wipe,

4. Alejò ati atipo li emi iṣe lọdọ nyin: ẹ fun mi ni ilẹ-isinku lãrin nyin, ki emi ki o le sin okú mi kuro ni iwaju mi.

5. Awọn ọmọ Heti si dá Abrahamu lohùn, nwọn si wi fun u pe,

6. Oluwa mi, gbọ́ ti wa: alagbara ọmọ-alade ni iwọ lãrin wa: ninu ãyò bojì wa ni ki o sin okú rẹ; kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio fi ibojì rẹ̀ dù ọ, ki iwọ ki o má sin okú rẹ.

7. Abrahamu si dide duro, o si tẹriba fun awọn enia ilẹ na, fun awọn ọmọ Heti.

8. O si ba wọn sọ̀rọ wipe, Bi o ba ṣe pe ti inu nyin ni ki emi ki o sin okú mi kuro ni iwaju mi, ẹ gbọ́ ti emi, ki ẹ si bẹ̀ Efroni, ọmọ Sohari, fun mi,

9. Ki o le fun mi ni ihò Makpela, ti o ni, ti o wà li opinlẹ oko rẹ̀; li oju-owo ni ki o fifun mi, fun ilẹ-isinku lãrin nyin.

10. Efroni si joko lãrin awọn ọmọ Heti: Efroni, ọmọ Heti, si dá Abrahamu lohùn li eti gbogbo awọn ọmọ Heti, ani li eti gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀ wipe,

Gẹn 23