Gẹn 21:30-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. O si wipe, nitori abo ọdọ-agutan meje yi ni iwọ o gbà lọwọ mi, ki nwọn ki o le ṣe ẹrí mi pe, emi li o wà kanga yi.

31. Nitorina li o ṣe pè ibẹ̀ na ni Beer-ṣeba; nitori nibẹ̀ li awọn mejeji gbé bura.

32. Bẹ̃ni nwọn si dá majẹmu ni Beer-ṣeba: nigbana li Abimeleki dide, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilẹ awọn ara Filistia.

33. Abrahamu si lọ́ igi tamariski kan ni Beer-ṣeba, nibẹ̀ li o si pè orukọ OLUWA, Ọlọrun Aiyeraiye.

34. Abrahamu si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọjọ́ pupọ̀.

Gẹn 21