20. Emi si ti gbọ́ adura rẹ fun Iṣmaeli: kiyesi i, emi o si busi i fun u, emi o si mu u bisi i, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi; ijoye mejila ni on o bí, emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla:
21. Ṣugbọn majẹmu mi li emi o ba Isaaki dá, ẹniti Sara yio bí fun ọ li akoko iwoyi amọ́dun.
22. O si fi i silẹ li ọ̀rọ iba a sọ, Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ Abrahamu.
23. Abrahamu si mu Iṣmaeli, ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin ti a bí ni ile rẹ̀, ati gbogbo awọn ti a fi owo rẹ̀ rà, gbogbo ẹniti iṣe ọkunrin ninu awọn enia ile Abrahamu; o si kọ wọn ni ilà ara li ọjọ́ na gan, bi Ọlọrun ti sọ fun u.
24. Abrahamu si jẹ ẹni ọkandilọgọrun ọdún, nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀.
25. Ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ ẹni ọdún mẹtala nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀.
26. Li ọjọ́ na gan li a kọ Abrahamu ni ilà, ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin.
27. Ati gbogbo awọn ọkunrin ile rẹ̀, ti a bi ninu ile rẹ̀, ati ti a si fi owo rà lọwọ alejò, ni a kọ ni ilà pẹlu rẹ̀.