10. Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari.
11. Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó.
12. Ati Reseni lagbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla.
13. Misraimu si bí Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu,
14. Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu.