1. IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi.
2. Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi.
3. Ati awọn ọmọ Gomeri, Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma.