26. Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.
27. Nitoripe iye ẹnyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ̀.
28. Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu.
29. Bi ẹnyin ba si jẹ ti Kristi, njẹ ẹnyin ni irú-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri.