1. LẸHIN ọdún mẹrinla, nigbana ni mo tún gòke lọ si Jerusalemu pẹlu Barnaba, mo si mu Titu lọ pẹlu mi.
2. Mo si gòke lọ nipa ifihan, mo si gbe ihinrere na kalẹ niwaju wọn ti mo nwasu larin awọn Keferi, ṣugbọn nikọ̀kọ fun awọn ti o jẹ ẹni-nla, ki emi kì o má ba sáre, tabi ki o má ba jẹ pe mo ti sáre lasan.
3. Ṣugbọn a kò fi agbara mu Titu ti o wà pẹlu mi, ẹniti iṣe ara Hellene, lati kọla:
4. Ati nitori awọn eke arakunrin ti a yọ́ mu wọ̀ inu wa wá, awọn ẹniti o yọ́ wa iṣe amí lati ri omnira wa, ti awa ni ninu Kristi Jesu, ki nwọn ki o le mu wa wá sinu ìde:
5. Awọn ẹniti awa kò si fi àye fun lati dari wa fun wakati kan; ki otitọ ìhinrere ki o le mã wà titi pẹlu nyin.
6. Ṣugbọn niti awọn ti o dabi ẹni nla, ohunkohun ti o wù ki nwọn jasi, kò jẹ nkankan fun mi: Ọlọrun kò ṣe ojuṣãju ẹnikẹni: ani awọn ti o dabi ẹni-nla, kò kọ́ mi ni nkankan.
7. Ṣugbọn kàkà bẹ̃, nigbati nwọn ri pe a ti fi ihinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi ihinrere ti awọn onila le Peteru lọwọ;
8. (Nitori ẹniti o ṣiṣẹ ninu Peteru si iṣẹ Aposteli ti ikọla, on kanna li o ṣiṣẹ ninu mi fun awọn Keferi pẹlu),