18. Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun.
19. Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu.
20. Ṣugbọn ogo ni fun Ọlọrun ati Baba wa lai ati lailai. Amin.
21. Ẹ kí olukuluku enia mimọ́ ninu Kristi Jesu. Awọn ara ti o wà pẹlu mi kí nyin.