25. Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi.
26. Nitoriti ọkàn rẹ̀ fà si gbogbo nyin, o si kún fun ibanujẹ, nitoriti ẹnyin ti gbọ́ pe on ti ṣe aisan.
27. Nitõtọ li o ti ṣe aisan titi de oju ikú: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣãnu fun u; kì si iṣe fun on nikan, ṣugbọn fun mi pẹlu, ki emi ki o màṣe ni ibanujẹ lori ibanujẹ.
28. Nitorina ni mo ṣe fi titara-titara rán a, pe nigbati ẹnyin ba si tún ri i, ki ẹnyin ki o le yọ̀, ati ki ibanujẹ mi ki o le dínkù.
29. Nitorina ẹ fi ayọ̀ pupọ gbà a nipa ti Oluwa; ki ẹ si ma bù ọlá fun irú awọn ẹni bẹ̃:
30. Nitoripe nitori iṣẹ Kristi li o ṣe sunmọ ẹnu-ọ̀na ikú, ti kò si kà ẹmí ara rẹ̀ si, lati mu aitó iṣẹ isin nyin si mi kun.