Filp 2:18-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Bakanna ni ki ẹnyin ki o mã yọ̀, ki ẹ si mã ba mi yọ̀ pẹlu.

19. Ṣugbọn mo ni ireti ninu Jesu Oluwa, lati rán Timotiu si nyin ni lọ̃lọ yi, ki emi pẹlu le ni ifọkanbalẹ nigbati mo ba gburó ijoko nyin.

20. Nitori emi kò ni ẹni oninu kanna ti o dabi rẹ̀, ti yio ma fi tinutinu ṣe aniyan nyin.

21. Nitori gbogbo wọn ni ntọju nkan ti ara wọn, kì iṣe nkan ti iṣe ti Jesu Kristi.

22. Ṣugbọn ẹnyin ti mọ̀ ọ dajudaju, pe gẹgẹ bi ọmọ lọdọ baba rẹ̀, bẹ̃li o si ti mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere.

23. Nitorina on ni mo ni ireti lati rán si nyin nisisiyi, nigbati mo ba woye bi yio ti ri fun mi.

24. Ṣugbọn mo gbẹkẹle Oluwa, pe emi tikarami pẹlu yio wá ni lọ̃lọ.

25. Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi.

26. Nitoriti ọkàn rẹ̀ fà si gbogbo nyin, o si kún fun ibanujẹ, nitoriti ẹnyin ti gbọ́ pe on ti ṣe aisan.

Filp 2