Filp 2:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.

12. Nitorina ẹnyin olufẹ mi, gẹgẹ bi ẹnyin ti ngbọran nigbagbogbo, kì iṣe nigbati mo wà lọdọ nyin nikan, ṣugbọn papa nisisiyi ti emi kò si, ẹ mã ṣiṣẹ igbala nyin yọri pẹlu ìbẹru ati iwarìri,

13. Nitoripe Ọlọrun ni nṣiṣẹ ninu nyin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ifẹ inu rere rẹ̀.

14. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan.

15. Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye;

16. Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan.

17. Ani, bi a tilẹ tú mi dà sori ẹbọ ati iṣẹ isin igbagbọ́ nyin, mo yọ̀, mo si mba gbogbo nyin yọ̀ pẹlu.

Filp 2