Filp 2:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà,

2. Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan.

3. Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.

4. Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.

5. Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu:

6. Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba:

7. Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia.

8. Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu.

9. Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ:

10. Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ;

Filp 2