26. Ki iṣogo nyin ki o le di pupọ gidigidi ninu Jesu Kristi ninu mi nipa ipada wá mi sọdọ nyin.
27. Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan;
28. Ki ẹ má si jẹ ki awọn ọta dẹruba nyin li ohunkohun: eyiti iṣe àmi ti o daju fun iparun wọn, ṣugbọn ti igbala nyin, ati eyini ni lati ọwọ́ Ọlọrun wá.
29. Nitori niti Kristi, ẹnyin li a ti yọnda fun, kì iṣe lati gbà a gbọ́ nikan, ṣugbọn lati jìya nitori rẹ̀ pẹlu:
30. Ẹ si ni ìja kanna ti ẹnyin ti ri ninu mi, ti ẹnyin si gbọ́ nisisiyi pe o wà ninu mi.