14. Ati pe ọ̀pọlọpọ awọn arakunrin ninu Oluwa, ti o ni igbẹkẹle si ìde mi nfi igboiya gidigidi sọrọ Ọlọrun laibẹru.
15. Nitotọ awọn ẹlomiran tilẹ nfi ija ati ilara wasu Kristi; awọn ẹlomiran si nfi inu rere ṣe e.
16. Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi:
17. Awọn kan ẹwẹ si nfi ifẹ ṣe e, nitoriti nwọn mọ̀ pe a gbe mi dide fun idahun-ẹjọ ihinrere.
18. Njẹ kini? bikoṣepe nibi gbogbo, iba ṣe niti àfẹ̀tànṣe tabi niti otitọ, a sa nwasu Kristi; emi si nyọ̀ nitorina, nitõtọ, emi ó si ma yọ̀.
19. Nitoriti mo mọ̀ pe eyi ni yio yọri si igbala fun mi lati inu adura nyin wá, ati ifikún Ẹmí Jesu Kristi,