Filp 1:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PAULU ati Timotiu, awọn iranṣẹ Jesu Kristi, si gbogbo awọn enia mimọ́ ninu Kristi Jesu ti o wà ni Filippi, pẹlu awọn biṣopu ati awọn diakoni:

2. Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi.

3. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe,

4. Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ̀ bẹ̀bẹ,

Filp 1