Est 7:3-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbana ni Esteri ayaba dahùn wi pe, bi mo ba ri ore-ọfẹ loju rẹ ọba, bi o ba si wù ọba, mo bẹbẹ ki a fi ẹmi mi bùn mi nipa ẹbẹ mi, ati awọn enia mi nipa ibère mi.

4. Nitori a ti tà wa, emi ati awọn enia mi, lati run wa, lati pa wa, ki a le parun. Ṣugbọn bi o ṣe pe, a ti tà wa fun ẹrúkunrin, ati ẹrúbirin ni, emi iba pa ẹnu mi mọ́, bi o tilẹ jẹ pe ọta na kò le di ofò ọba.

5. Nigbana ni Ahaswerusi ọba dahùn, o si wi fun Esteri ayaba pe, Tali oluwa rẹ̀ na, nibo li o si wà, ti o jẹ gbe e le ọkàn rẹ̀ lati ṣe bẹ̃?

6. Esteri si wi pe, ọlọtẹ enia ati ọta na ni Hamani, ẹni buburu yi. Nigbana ni ẹ̀ru ba Hamani niwaju ọba ati ayaba.

7. Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on.

Est 7