6. Bẹ̃ni Hamani si wọle wá, Ọba si wi fun u pe, kini a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun? Njẹ Hamani rò ninu ọkàn ara rẹ̀ pe, Tani inu ọba le dùn si lati bù ọlá fun jù emi tikalami lọ?
7. Hamani si da ọba lohùn pe, ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
8. Jẹ ki a mu aṣọ ọba ti ọba ima wọ̀, ati ẹṣin ti ọba ima gùn, ati ade ọba ti ima gbe kà ori rẹ̀ wá;
9. Ki a si fi ẹ̀wu ati ẹṣin yi le ọwọ ọkan ninu awọn ijoye ọba ti o lọlajùlọ, ki nwọn fi ṣe ọṣọ fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun, ki o si mu u gẹṣin là igboro ilu, ki o si ma kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.