5. Nigbana ni ọba wi pe, ẹ mu ki Hamani ki o yara, ki on ki o le ṣe bi Esteri ti wi. Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá si àse na ti Esteri ti sè silẹ.
6. Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e.
7. Nigbana ni Esteri dahùn, o si wi pe, ẹ̀bẹ mi ati ibère mi ni pe,
8. Bi mo ba ri ore-ọfẹ loju ọba, bi o ba si wù ọba lati fi ohun ti emi ntọrọ fun mi, ati lati ṣe ohun ti emi mbère fun mi, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá si àse ti emi o si tun sè fun wọn, emi o si ṣe li ọla bi ọba ti wi.