Est 4:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Hataki si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ Mordekai fun Esteri.

10. Esteri si tun sọ fun Hataki, o si rán a si Mordekai.

11. Pe, gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ati awọn enia ìgberiko ọba li o mọ̀ pe, ẹnikẹni ibaṣe ọkunrin tabi obinrin, ti o ba tọ̀ ọba wá sinu àgbala ti inu, ti a kò ba pè, ofin rẹ̀ kan ni, ki a pa a, bikoṣe iru ẹniti ọba ba nà ọpá alade wura si, ki on ki o le yè: ṣugbọn a kò ti ipè mi lati wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ lati ìwọn ọgbọn ọjọ yi wá.

12. Nwọn si sọ ọ̀rọ Esteri fun Mordekai.

13. Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ.

Est 4