1. LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀.
2. Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u.