Est 2:12-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Njẹ nigbati o kan olukuluku wundia lati wọ̀ ile tọ̀ Ahaswerusi ọba lọ, lẹhin igbati on ba ti gbe oṣù mejila, gẹgẹ bi iṣe awọn obinrin, (nitori bayi ni ọjọ ìwẹnumọ́ wọn pari, oṣù mẹfa ni nwọn fi ikùn òroro ojiá, ati oṣù mẹfa òroro olõrùn didùn, ati pẹlu ohun elo ìwẹnumọ́ awọn obinrin):

13. Bayi ni wundia na iwá si ọdọ ọba; ohunkohun ti o ba bère li a si ifi fun u lati ba a lọ, lati ile awọn obinrin lọ si ile ọba.

14. Li aṣãlẹ on a lọ, ni õrọ ijọ keji on a si pada si ile keji ti awọn obinrin, si ọwọ Ṣaaṣgasi, ìwẹfa, ọba, ti nṣe olutọju awọn obinrin, on kò si gbọdọ wọle tọ̀ ọba wá mọ, bikoṣepe inu ọba ba dùn si i, ti a ba si pè e li orukọ.

Est 2