Est 2:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN nkan wọnyi, nigbati ibinu Ahaswerusi ọba wa tuka, o ranti Faṣti, ati ohun ti o ti ṣe, ati aṣẹ ti a ti pa nitori rẹ̀.

2. Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba, ti nṣe iranṣẹ fun u, wi pe, jẹ ki a wá awọn wundia ti o li ẹwà fun ọba.

3. Ki ọba ki o si yàn olori ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣà awọn wundia ti o li ẹwà jọ wá si Ṣuṣani ãfin, si ile awọn obinrin, si ọdọ Hegai, ìwẹfa ọba olutọju awọn obinrin; ki a si fi elo ìwẹnumọ́ wọn fun wọn:

4. Ki wundia na ti o ba wù ọba ki o jẹ ayaba ni ipò Faṣti. Nkan na si dara loju ọba, o si ṣe bẹ̃.

5. Ọkunrin ara Juda kan wà ni Ṣuṣani ãfin, orukọ ẹniti ijẹ Mordekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣemei, ọmọ Kisi, ara Benjamini.

6. Ẹniti a ti mu lọ lati Jerusalemu pẹlu ìgbekun ti a kó lọ pẹlu Jekoniah, ọba Juda, ti Nebukadnessari, ọba Babeli ti kó lọ.

Est 2