Est 1:20-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ati nigbati a ba si kede aṣẹ ọba ti on o pa yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, (nitori on sa pọ̀) nigbana ni gbogbo awọn obinrin yio ma bọ̀wọ fun ọkọ wọn, ati àgba ati ewe.

21. Ọ̀rọ na si dara loju ọba ati awọn ijoye; ọba si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Memukani:

22. Nitori on ran ìwe si gbogbo ìgberiko ọba, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède rẹ̀, ki olukulùku ọkunrin ki o le ṣe olori ni ile tirẹ̀, ati ki a le kede rẹ̀ gẹgẹ bi ède enia rẹ̀.

Est 1