3. Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah, ti awọn ọmọ Paroṣi, Ṣekariah: ati pẹlu rẹ̀ li a ka ãdọjọ ọkunrin nipa iwe itan-idile.
4. Ninu awọn ọmọ Pahat-moabu; Elihoenai ọmọ Serahiah, ati pẹlu rẹ̀, igba ọkunrin.
5. Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah; ọmọ Jahasieli, ati pẹlu rẹ̀, ọdunrun ọkunrin.
6. Ninu awọn ọmọ Adini pẹlu, Ebedi ọmọ Jonatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọta ọkunrin.
7. Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Jeṣaiah ọmọ Ataliah, ati pẹlu rẹ̀, ãdọrin ọkunrin.
8. Ati ninu awọn ọmọ Ṣefatiah; Sebadiah ọmọ Mikaeli, ati pẹlu rẹ̀, ọgọrin ọkunrin.
9. Ninu awọn ọmọ Joabu; Obadiah ọmọ Jahieli ati pẹlu rẹ̀, ogunlugba ọkunrin o din meji.