Nigbana ni mo kede àwẹ kan nibẹ lẹba odò Ahafa, ki awa ki o le pọn ara wa loju niwaju Ọlọrun wa, lati ṣafẹri ọ̀na titọ́ fun wa li ọwọ rẹ̀, ati fun ọmọ wẹrẹ wa, ati fun gbogbo ini wa.