17. Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu.
18. Ati ohunkohun ti o ba wu ọ, ati awọn arakunrin rẹ lati fi fàdaka ati wura iyokù ṣe, eyini ni ki ẹnyin ki o ṣe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun nyin.
19. Ohun-èlo wọnni ti a fi fun ọ pẹlu fun ìsin ile Ọlọrun rẹ, ni ki iwọ ki o fi lelẹ niwaju Ọlọrun ni Jerusalemu.
20. Ati ohunkohun ti a ba fẹ pẹlu fun ile Ọlọrun rẹ, ti iwọ o ri àye lati nawo rẹ̀, nawo rẹ̀ lati inu ile iṣura ọba wá.
21. Ati emi, ani Artasasta ọba paṣẹ fun gbogbo awọn olutọju iṣura, ti o wà li oke odò pe, ohunkohun ti Esra alufa, ti iṣe akọwe ofin Ọlọrun ọrun yio bère lọwọ nyin, ki a ṣe e li aijafara,
22. Titi de ọgọrun talenti fàdaka, ati de ọgọrun oṣuwọn alikama, ati de ọgọrun bati ọti-waini, ati de ọgọrun bati ororo, ati iyọ laini iye.
23. Ohunkohun ti Ọlọrun ọrun palaṣẹ, ki a fi otitọ ṣe e fun ile Ọlọrun ọrun: ki ibinu ki o má de si ijọba ọba, ati awọn ọmọ rẹ̀.