1. NIGBANA ni Dariusi ọba paṣẹ, a si wá inu ile ti a ko iwe jọ si, nibiti a to iṣura jọ si ni Babiloni.
2. A si ri iwe kan ni Ekbatana, ninu ilu olodi ti o wà ni igberiko Medea, ati ninu rẹ̀ ni iwe-iranti kan wà ti a kọ bayi:
3. Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ.
4. Ilè okuta nla mẹta, ati ilè igi titun kan: ki a si ṣe inawo rẹ̀ lati inu ile ọba wa: