12. Ṣugbọn nitoriti awọn baba wa mu Ọlọrun ọrun binu, o fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babiloni ti Kaldea, ẹniti o wó ile yi palẹ, ti o si kó awọn enia na lọ si Babiloni.
13. Ṣugbọn li ọdun ekini Kirusi ọba Babiloni, Kirusi ọba na fi aṣẹ lelẹ lati kọ́ ile Ọlọrun yi.
14. Pẹlupẹlu ohun èlo wura ati ti fàdaka ti ile Ọlọrun ti Nebukadnessari ko lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si mu lọ sinu tempili Babiloni, awọn na ni Kirusi ọba ko lati inu tempili Babiloni jade, a si fi wọn le ẹnikan lọwọ, orukọ ẹniti ijẹ Ṣeṣbassari, ẹniti on fi jẹ bãlẹ;
15. On si wi fun u pe, Kó ohun èlo wọnyi lọ, ki o fi wọn si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, ki o si mu ki a tun kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.