Esr 5:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN awọn woli, Haggai woli, ati Sekariah ọmọ Iddo, sọ asọtẹlẹ fun awọn Ju ti o wà ni Juda ati Jerusalemu li orukọ Ọlọrun Israeli.

2. Li akoko na ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki dide, nwọn si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Ọlọrun ni Jerusalemu; awọn woli Ọlọrun si wà pẹlu wọn ti nràn wọn lọwọ.

3. Li akoko kanna ni Tatnai, bãlẹ ni ihahin odò, ati Ṣetar-bosnai pẹlu awọn ẹgbẹ wọn, wá si ọdọ wọn, nwọn si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati tun odi yi ṣe?

Esr 5